Ọbadiah Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ọbadiah ìránṣẹ́ Olúwa sọ nípa ìṣubú tó ń bọ̀ wá sórí Edomu. Ó jẹ́ kí a rí i pé Edomu gbéraga lórí ààbò rẹ̀. Níwọ́n ìgbà tí Edomu ti ṣe èyí, wọn ṣe ohun tó burú níwájú Olúwa, Ọlọ́run sì mú ìbínú wa sórí wọn. Olúwa wí pé òun yóò pa wọ́n run, ṣùgbọ́n òun yóò gba orí òkè Sioni àti Israẹli là, ìjọba Ọlọ́run yóò sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀.
Kókó kan pàtàkì ti ìwé yìí fẹ́ kí a mọ́ ní pe, Edomu kùnà pátápátá, wọn kò ran Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì dá ìjà sílẹ̀. Nítorí pé Ọlọ́run kọ Esau, kò sì ṣí ọ̀nà tí yóò fi gbé àwọn ọmọ Edomu ga. Edomu sá wọ inú òkè agbára lọ, wọn kì yóò sì ní ibùgbé. Ṣùgbọ́n Israẹli yóò ṣe rere nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Àkọlé àti ìbẹ̀rẹ̀ 1.
ii. Ìdájọ́ lórí Edomu 2-14.
iii. Ọjọ́ Olúwa 15-21.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Ọbadiah Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀