Matiu 24:15-35

Matiu 24:15-35 YCB

“Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, tí ó bá dúró ní ibi mímọ́, (ẹni tí ó bá kà á, kí òye kí ó yé e). Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn tí ó wà ní Judea sálọ sí àwọn orí òkè. Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn. Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ loyan ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì! Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi. Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí. “Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú. Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kristi náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́. Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ. Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀. “Nítorí náà, bí ẹnìkan bá sọ fún yín pé, ‘Olùgbàlà ti dé,’ àti pé, ‘Ó wà ní aginjù,’ ẹ má ṣe wàhálà láti lọ wò ó, tàbí tí wọ́n bá ní ó ń fi ara pamọ́ sí iyàrá, ẹ má ṣe gbà wọn gbọ́. Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́. Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọpọ̀ sí. “Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, “ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn; àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀, agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’ “Nígbà náà ni ààmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá. Yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohùn ìpè ńlá, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti ọ̀run jọ. “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́: Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ tuntun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadàbọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò kọjá títí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.

Àwọn fídíò fún Matiu 24:15-35