Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an. “Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni: Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i. Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni Sinagọgu. Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní ‘Rabbi.’ “Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Rabbi, nítorí pé ẹnìkan ni Olùkọ́ yín, àní Kristi, ará sì ni gbogbo yín. Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run. Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kristi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá pọ̀jù nínú yín, ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ yín. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara wọn sílẹ̀ ni a ó gbéga.
Kà Matiu 23
Feti si Matiu 23
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Matiu 23:4-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò