Bí wọ́n ti súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé itòsí ìlú Betfage ní orí òkè Olifi, Jesu sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì, Ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tó wà ni tòsí yín, ẹ̀yin yóò rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ti wọ́n so pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. Bí ẹnikẹ́ni bá sì béèrè ìdí tí ẹ fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sá à wí pé, Olúwa fẹ́ lo wọn, òun yóò sì rán wọn lọ.” Èyí ṣẹlẹ̀ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì ṣẹ pé: “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé, ‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ”
Kà Matiu 21
Feti si Matiu 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Matiu 21:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò