Matiu 15:10-14

Matiu 15:10-14 YCB

Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ó wí pé, “Ẹ tẹ́tí, ẹ sì jẹ́ kí nǹkan tí mo sọ yé yín. Ènìyàn kò di ‘aláìmọ́’ nípa ohun tí ó wọ ẹnu ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti ẹnu jáde wá ni ó sọ ní di ‘aláìmọ́.’ ” Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ mọ̀ pé inú bí àwọn Farisi lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó sọ yìí?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi ti ń bẹ ni ọ̀run kò bá gbìn ni á ó fàtu tigbòǹgbò tigbòǹgbò, Ẹ fi wọ́n sílẹ̀; afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò.”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ