Jesu tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí àgbẹ̀ kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀; Ṣùgbọ́n ní òru ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá sí oko náà ó sì gbin èpò sáàrín alikama, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Nígbà tí alikama náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, tí ó sì so èso, nígbà náà ni èpò náà fi ara hàn.
“Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àgbẹ̀ náà wá, wọ́n sọ fún un pé, ‘Ọ̀gá, irúgbìn rere kọ́ ni ìwọ ha gbìn sí oko rẹ nì? Báwo ni èpò ṣe wà níbẹ̀ nígbà náà?’
“Ó sọ fún wọn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’
“Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tún bí i pé, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ kí a fa èpò náà tu kúrò?’
“Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá, nítorí bí ẹ̀yin bá ń tu èpò kúrò, ẹ ó tu alikama dànù pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì máa dàgbà pọ̀, títí di àsìkò ìkórè. Èmi yóò sọ fún àwọn olùkórè náà láti kọ́kọ́ ṣa àwọn èpò kúrò kí wọ́n sì dìwọ́n ní ìtí, kí a sì sun wọn, kí wọ́n sì kó alikama sínú àká mi.’ ”
Jesu tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí èso hóró musitadi, èyí tí ọkùnrin kan mú tí ó gbìn sínú oko rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ èso tí ó kéré púpọ̀ láàrín èso rẹ̀, síbẹ̀ ó wá di ohun ọ̀gbìn tí ó tóbi jọjọ. Ó sì wá di igi tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì wá, wọ́n sì fi ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé.”
Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí ìwúkàrà tí obìnrin kan mú tí ó pò mọ́ ìyẹ̀fun púpọ̀ títí tí gbogbo rẹ fi di wíwú.”
Òwe ni Jesu fi sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, òwe ni ó fi bá wọn sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ. Kí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì sọ lé wá sí ìmúṣẹ pé:
“Èmi yóò ya ẹnu mi láti fi òwe sọ̀rọ̀.
Èmi yóò sọ àwọn ohun tí ó fi ara sin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá.”
Lẹ́yìn náà ó sì fi ọ̀pọ̀ ènìyàn sílẹ̀ lóde, ó wọ ilé lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn wí pé, “Ṣàlàyé òwe èpò inú oko fún wa.”
Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ọmọ ènìyàn ni ẹni tí ó ń fúnrúgbìn rere. Ayé ni oko náà; irúgbìn rere ni àwọn ènìyàn ti ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ti èṣù, ọ̀tá tí ó gbin àwọn èpò sáàrín alikama ni èṣù. Ìkórè ni òpin ayé, àwọn olùkórè sì ní àwọn angẹli.
“Gẹ́gẹ́ bí a ti kó èpò jọ, tí a sì sun ún nínú iná, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Ọmọ Ènìyàn yóò ran àwọn angẹli rẹ̀, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tó ń mú ni dẹ́ṣẹ̀ kúrò ní ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn búburú. Wọn yóò sì sọ wọ́n sí inú iná ìléru, níbi ti ẹkún òun ìpayínkeke yóò gbé wà. Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò máa ràn bí oòrùn ní ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá létí, jẹ́ kí ó gbọ́.
“Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà.
“Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà. Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á.