Matiu 10:28-31

Matiu 10:28-31 YCB

Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa Ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì. Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin. Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé. Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.

Àwọn fídíò fún Matiu 10:28-31