Ẹkun Jeremiah Ìfáàrà

Ìfáàrà
Gbogbo Ìwé Ẹkún Jeremiah jẹ́ ewì. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwé márààrún ní ẹsẹ méjìlélógún, yàtọ̀ sí orí kẹta tí ó ní ẹsẹ mẹ́rìn-dínláàdọ́rin tí ó jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta àwọn ẹkún tókù. Ẹkún mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àkọ́kọ́ gùn bákan náà, ní ẹsẹ kìn-ín-ní àti èkejì ọ̀kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ sí (1.7) Wọ́n ní ìlà mẹ́ta mẹ́ta bi ewì àwọn Heberu, nígbà tí ìlà kẹta ọ̀kọ̀ọ̀kan tó ní ẹsẹ mẹ́rìn-dínláàdọ́rin ní ìlà Heberu kan. Lílo àwọn álífábẹ́tì ní ìlànà tí ó tọ́ ṣàlàyé bí ẹkún yìí ṣe rí, ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.
Ìwé ẹkún Jeremiah nìkan ni gbogbo ìwé rẹ̀ jẹ́ ẹkún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé wòlíì mìíràn náà ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ìwé wọn ló kún fún ẹkún bí, ti Jeremiah. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe dárò púpọ̀ lórí ìparun Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ó sọkún fún ìparun Uri, Ṣumeri àti Nipuri. Ìwé yìí tún sọ pàtàkì ìṣe àwọn ìjọ àgùdà níbi tí a ti ka ọjọ́ mẹ́ta tí ó gbẹ̀yìn ọ̀sẹ̀ sí mímọ́. Iṣẹ́ wọn yìí mú kí a rántí bí Ìwé Ẹkún Jeremiah ṣe ṣàlàyé ìparun Jerusalẹmu wí pé kì í ṣe fún òun nìkan bí kò ṣe láti kọ́ ọgbọ́n nínú rẹ̀. Ó tún jẹ́ kí ó yé ni pé ìwé náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹkún (1.1-2) ṣùgbọ́n ìparí rẹ̀ jẹ́ ìrònúpìwàdà (5.21-22). Ó sì tún sọ̀rọ̀ dídára rere Ọlọ́run, pé òun ni Olúwa ìrètí (3.21,24-25), Ìfẹ́ (3.22) ìgbàgbọ́ (3.23) àti ti ìgbàlà (3.26).
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìbànújẹ́ àti ìparun Jerusalẹmu 1.
ii. Ìbínú Olúwa sí àwọn ènìyàn rẹ̀ 2.
iii. Ìráhùn àwọn Juda àti ọ̀nà fún ìmọ́kànle 3.
iv. Ìyàtọ̀ láàrín àtijọ́ àti ìsinsin yìí Sioni 4.
v. Juda bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì Ọlọ́run 5.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Ẹkun Jeremiah Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀