Joṣua Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìgbé ayé Joṣua kún fún òtítọ́, onírúurú àṣeyọrí àti ìbọ̀wọ̀ fún. A mọ̀ ọ́n fún ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó jinlẹ̀ nínú Ọlọ́run àti bí ọkùnrin tí ó wà nínú ẹ̀mí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, ó gbé ìgbé ayé tó korò ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Ejibiti, ó rí agbára ńlá àti iṣẹ́ ìyanu bí àwọn ọmọ Israẹli ṣe bọ́ lọ́wọ́ ogun àwọn ọmọ Ejibiti nígbà tí omi Òkun pínyà níwájú wọn. Nígbà tí wọ́n wà ní Sinai, Joṣua ló tún darí àwọn ọmọ Israẹli láti ṣẹ́gun àwọn Amaleki. Òun nìkan ni ó tún tẹ̀lé Mose lọ sí orí òkè mímọ́ níbi tí wọ́n ti gba àpáta òfin. Joṣua ni ẹni tí a yàn láti ṣojú ìran tirẹ̀ Efraimu nígbà tí a rán ayọ́lẹ̀wò méjìlá lọ sí Kenaani láti lọ wo ilẹ̀ wọn. Júù gbogbo rẹ̀ lọ, ìránṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn ló jẹ́ láti mú kí iṣẹ́ Mose parí àti láti mú kí àwọn ọmọ Israẹli dé ilẹ̀ ìlérí.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Wíwọ ilẹ̀ náà 1.1–5.12.
ii. Gbígba ilẹ̀ náà 5.13–12.24.
iii. Pínpín ilẹ̀ náà 13–21.
iv. Ìsọ̀kan àti òtítọ́ sí Olúwa 22–24.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joṣua Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀