Joṣua 21:27-45

Joṣua 21:27-45 YCB

Àwọn ọmọ Gerṣoni ìdílé àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n fún lára: ìdajì ẹ̀yà Manase, Golani ní Baṣani (ìlú ààbò fún apànìyàn) àti Be-Eṣterah pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọ́n jẹ́ méjì; Láti ara ẹ̀yà Isakari ni wọ́n ti fún wọn ní, Kiṣioni Daberati, Jarmatu àti Eni-Gannimu, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin. Láti ara ẹ̀yà Aṣeri ni wọ́n ti fún wọn ní Miṣali, àti Abdoni, Helikati àti Rehobu, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin; Láti ara ẹ̀yà Naftali ni a ti fún wọn ní: Kedeṣi ní Galili (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Hamoti Dori àti Karitani, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́ta. Gbogbo ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Gerṣoni jẹ́ mẹ́tàlá, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn. Láti ara ẹ̀yà Sebuluni ni a ti fún ìdílé Merari (tí í ṣe ìyókù ọmọ Lefi) ní: Jokneamu, Karta, Dimina àti Nahalali, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin. Láti ara ẹ̀yà Reubeni ni wọ́n ti fún wọn ní Beseri, àti Jahisa, Kedemoti àti Mefaati, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin. Láti ara ẹ̀yà Gadi ni wọ́n ti fún wọn ní Ramoti ní Gileadi (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Mahanaimu, Heṣboni àti Jaseri, e pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin. Gbogbo ìlú tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Merari tí wọ́n jẹ́ ìyókù àwọn ọmọ Lefi jẹ́ méjìlá. Gbogbo ìlú àwọn ọmọ Lefi tó wà láàrín ara ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ méjì-dínláádọ́ta lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìlú wọ̀nyí ni ó ni ilẹ̀ pápá oko tí ó yí ì ká, bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún gbogbo ìlú wọ̀nyí. Báyìí ni OLúWA fún Israẹli ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí láti fi fún àwọn baba ńlá wọn. Nígbà tí wọ́n sì gbà á tan wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀. OLúWA sì fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún baba ńlá wọn. Kò sì sí ọ̀kankan nínú àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè dojúkọ wọ́n. OLúWA sì fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn ní ọwọ́. Kò sí ọ̀kan nínú ìlérí rere tí OLúWA ṣe fún ilé Israẹli tí ó kùnà; Gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe.