Jobu 33:15-18

Jobu 33:15-18 BMYO

Nínú àlá, ní ojúran òru, nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ, ní sísùn lórí ibùsùn, nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn, yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí, kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀; kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn; Ó sì fa ọkàn rẹ̀ padà kúrò nínú isà òkú, àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣègbé lọ́wọ́ idà.