Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe? Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè. Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”; omi Òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.” A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òṣùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀. A kò le è fi wúrà ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta Safire díye lé e. Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀. A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi; iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ. Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀. Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá? Tàbí níbo ni òye ń gbé? A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo, ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run. Ibi ìparun àti ikú wí pé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀. Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé. Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run, Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fi òṣùwọ̀n wọ́n omi. Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò, tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá, Nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde; ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí. Àti fún ènìyàn ni ó wí pé, “Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n, àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”
Kà Jobu 28
Feti si Jobu 28
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jobu 28:12-28
5 Days
Seeking Daily the Heart of God is a 5 day reading plan intended to encourage, challenge, and help us along the path of daily living. As Boyd Bailey has said, "Seek Him even when you don't feel like it, or when you are too busy and He will reward your faithfulness." The Bible says, "Blessed are they who keep his statutes and seek him with all their heart." Psalm 119:2
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò