Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní Òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá. Ṣùgbọ́n ahọ́n ni ẹnikẹ́ni kò le tù lójú; ohun búburú aláìgbọ́ràn ni, ó kún fún oró ikú tí í pa ni. Òun ni àwa fi ń yin Olúwa àti Baba, òun ni a sì fi ń bú ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run. Láti ẹnu kan náà ni ìyìn àti èébú ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, nǹkan wọ̀nyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀. Orísun odò kan a ha máa sun omi dídára àti omi iyọ̀ jáde láti orísun kan náà bí? Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ha le so èso olifi bí? Tàbí àjàrà ha lè so èso ọ̀pọ̀tọ́? Bẹ́ẹ̀ ni orísun kan kò le sun omíró àti omi tútù.
Kà Jakọbu 3
Feti si Jakọbu 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jakọbu 3:7-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò