Isaiah 14:3-23

Isaiah 14:3-23 YCB

Ní ọjọ́ tí OLúWA yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà, ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé: Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin! Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí! OLúWA ti dá ọ̀pá ìkà náà, ọ̀pá àwọn aláṣẹ, èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀ pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró, nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin. Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà, wọ́n bú sí orin. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn igi kedari ti Lebanoni ń yọ̀ lórí rẹ wí pé, “Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí, kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.” Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀ ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè. Gbogbo wọn yóò dáhùn, wọn yóò wí fún ọ wí pé, “Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ìwọ náà ti dàbí wa.” Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì, pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ, àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀. Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá, ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà! A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé Ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí! Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé, “Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run; Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run, Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́. Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀; Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.” Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun. Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ, wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ: “Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù, tí ó sì pa ìlú ńláńlá rẹ̀ run tí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?” Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀. Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀sílẹ̀, àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀, àwọn tí idà ti gún, àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun. Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀, A kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn, nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́ o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ. Ìran àwọn ìkà ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́. Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn, wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀ kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú u wọn. “Èmi yóò dìde sókè sí wọn,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Babeli àti àwọn tí ó sálà, àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,” ni OLúWA wí. Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí àti sí irà; Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a, ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.