Isaiah 14:1-2

Isaiah 14:1-2 YCB

OLúWA yóò fi àánú hàn fún Jakọbu, yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí i yóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn. Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́n wọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn. Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin ní ilẹ̀ OLúWA. Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn wọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn.