Heberu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìfáàrà sí ìwé àwọn ará Heberu
A kọ lẹ́tà pàtàkì yìí sí àwọn Júù tí ó jẹ́ Kristiani tí wọn ń gbèrò láti padà sínú ìlànà ẹ̀sìn Júù àtijọ́. A kọ ọ́ láti fihàn wọ́n pé, nítorí ohun tí Kristi ti ṣe, kò sí ohun kan tó tún kàn wọ́n mọ nínú àwọn òfin àti ìlànà ẹ̀sìn Júù. Àkókò ìmúṣẹ ti dé; ohun asán ni yóò jẹ́ láti padà sínú ìgbé ayé àtijọ́ tí kò dára bi i ìgbé ayé títún tí a rí nínú ìyìnrere. Èyí jẹ́ ẹ̀rí, pé ní gbogbo ọ̀nà ni Kristi fi dára ju àwọn angẹli lọ, ó ju Mose lọ, ó sì jù gbogbo àwọn wòlíì inú májẹ̀mú láéláé lọ pẹ̀lú. Lẹ́tà yìí sọ nípa májẹ̀mú tí ó dára jùlọ, ó sì fi ẹbọ tí ó dára jùlọ fún ni. Ìlànà ẹ̀sìn Kristiani dára jù ìlànà ẹ̀sìn àtijọ́ lọ. Ohun tó fi ṣe ẹ̀rí èyí ni irú ìgbé ayé àwọn ẹni mímọ́ nínú májẹ̀mú láéláé tí ó jẹ́ ìtọ́sọ́nà òtítọ́ fún àwọn ènìyàn.
Ipò Kristi àti ìgbé ayé Kristiani ni ìwé yìí sọ̀rọ̀ lé lórí. Àwọn ìlànà ẹ̀sìn yòókù ní iye lórí ṣùgbọ́n a kò le fi wọn wé iṣẹ́ tí Ọlọ́run ṣe nínú Kristi. A kò le fi ẹ̀sìn Júù tó gbilẹ̀ nínú májẹ̀mú láéláé ṣe àfiwé rẹ̀. Kristi ni ẹni tó ṣiṣẹ́ Ọlọ́run ní ayé nípa kíkú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ láti ọ̀dọ̀ wa ni kí a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀. Bí a bá ní ìgbàgbọ́, a ti wọ inú ìlérí Ọlọ́run, a ó sì ní ìgbé ayé kíkún nísinsin yìí àti ní ayé tí ń bọ̀ pẹ̀lú.
Kókó-ọ̀rọ̀
Gíga Kristi 1.1–3.19.
Ìgbé ayé onígbàgbọ́ tí ó dára 4.1-13.
Kristi ga ju àwọn àlùfáà lọ 4.14–8.13.
Májẹ̀mú tí ó dára jùlọ 9.1–10.39.
Àwọn onígbàgbọ́ ńlá àtijọ́ 11.1-40.
Ìyanu fún Kristiani kọ̀ọ̀kan 12.1–13.19.
Ọ̀rọ̀ ìyànjú ìkẹyìn 13.20-25.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Heberu Ìfáàrà: BMYO

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀