Hagai Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìfáàrà sí ìwé Wòlíì Hagai
Gẹ́gẹ́ bí i ti Malaki ni Hagai ṣe kọ ìwé rẹ̀. Hagai lo àwọn ìbéèrè tó pọ̀ láti ṣàlàyé àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì nínú ìwé rẹ̀. Ó sì túnṣe àwọn àwítúnwí kọ̀ọ̀kan nínú ìwé rẹ̀ bí àpẹẹrẹ, “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín” (1.5,7). Àwọn apá ibi tí ó ṣe pàtàkì nínú ìwé yìí ni ó sọ nípa ọjọ́ bíbọ̀ Olúwa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wòlíì yìí máa ń ṣe àfiwé àwọn ìwé tókù.
Nínú ìwé májẹ̀mú láéláé, Hagai ló tẹ̀lé Obadiah nínú àwọn ìwé tí ó kéré jù, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ rẹ̀ kọ́ ló kéré jù, ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣe pàtàkì. Hagai sọ kedere nípa àtubọ̀tán àwọn aláìgbọ́ràn àti àwọn tó ń ṣe ìgbọ́ràn sí àṣẹ Ọlọ́run. Ó tún jẹ́ kí ó di mí mọ̀ pé, nígbà tí ènìyàn bá ń gbé Ọlọ́run àti ilé rẹ̀ ga, wọ́n di alábùkún fún. Ìgbọràn mú ìyànjú wá, ó sì tún fi agbára fún Ẹ̀mí Ọlọ́run.
Bákan náà, ó ṣe àlàyé lórí wíwá tí Messia yóò wá a. Wíwá rẹ̀ yóò kún fún ògo láti tún tẹmpili mọ. Olúwa ṣe Serubbabeli bí òrùka dídán rẹ̀, láti fihàn pé Messia yóò wá.
Kókó-ọ̀rọ̀
Iṣẹ́ àkọ́kọ́: Ìpè láti tún tẹmpili kọ́ 1.1-11.
Ìgbọ́ràn Serubbabeli àti àwọn ènìyàn 1.12-15.
Iṣẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kejì: Ògo yóò kún inú ilé náà 2.1-9.
Iṣẹ́ ẹ̀kẹ́ta: A sọ àwọn aláìmọ́ di mímọ́, a sì bùkún fún wọn 2.10-19.
Iṣẹ́ kẹrin: Ìlérí fún Serubbabeli 2.20-23.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Hagai Ìfáàrà: BMYO

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀