Nígbà tí odindi ọdún méjì sì ti kọjá, Farao lá àlá: ó rí ara rẹ̀ tó dúró ní etí odò Naili. Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko. Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Naili, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà. Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ. Nígbà náà ni Farao jí.
Ó sì tún padà sùn, ó sì lá àlá mìíràn: ó rí síírí ọkà méje tí ó kún, ó yómọ, ó sì dára, ó sì jáde lára igi ọkà kan ṣoṣo. Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yómọ, afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù. Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ (ọmọ rẹ̀ kò tóbi) wọ̀nyí sì gbé àwọn tí ó yómọ (ọmọ rẹ̀ tóbi) mì. Nígbà náà ni Farao jí lójú oorun, ó sì rí i pé àlá ni.
Ní òwúrọ̀, ọkàn rẹ̀ dàrú, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn onídán àti ọ̀mọ̀ran ilẹ̀ Ejibiti. Farao rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n kò rí ọ̀kan nínú wọn tí ó le sọ ìtumọ̀ àlá náà fún un.
Nígbà náà ni olórí agbọ́tí wí fún Farao pé, “Lónìí ni mo rántí ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nígbà kan tí Farao bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi èmi àti olórí alásè sínú ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lá àlá, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. Ọmọkùnrin ará Heberu kan tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa. A rọ́ àwọn àlá wa fún un, ó sì túmọ̀ wọn fún wa, ó sọ ìtumọ̀ àlá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un. Bí ó sì ti túmọ̀ àlá wọ̀nyí náà ni ohun gbogbo rí. A dá mi padà sí ipò mi, a sì so ọkùnrin kejì kọ́ sórí ọ̀wọ̀n.”
Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Josẹfu, wọn sì mú un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá síwájú Farao.
Farao wí fún Josẹfu, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀.”
Josẹfu dá Farao ní ohùn pé, “Kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fi ìdáhùn àlàáfíà fún Farao ní ìtumọ̀ àlá náà.”
Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Ní inú àlá mi, mo dúró ni etí bèbè odò Naili, sì kíyèsi i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀. Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógó, wọn kò sì lẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ tí n kò tí ì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Ejibiti. Àwọn màlúù tí ó rù tí kò sì lẹ́wà sì jẹ àwọn màlúù tí ó sanra tí ó kọ́ jáde nínú odò. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ́ wọ́n tan, kò sì ẹni tí ó le mọ̀ pé wọ́n jẹ ohunkóhun, nítorí wọn kò sanra sí i, wọn sì bùrẹ́wà síbẹ̀. Nígbà náà ni mo tají.
“Ní ojú àlá mi, mo tún rí síírí ọkà méje tí ó yó ọmọ tí ó sì dára, wọ́n jáde láti ara igi ọkà kan. Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán. Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì. Mo sọ àlá yìí fún àwọn onídán mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”
Nígbà náà ni Josẹfu wí fún Farao, “Ìtumọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Farao. Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, síírí ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni. Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni síírí ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ dànù tan: Wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú.
“Bí mo ti wí fún Farao ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Farao. Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ̀ yanturu ń bọ̀ wà ní Ejibiti. Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú ń bọ̀, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé gbogbo ọ̀pọ̀ ní ilẹ̀ Ejibiti, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà, A kò ní rántí àsìkò ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu náà mọ́ nítorí pé ìyàn tí yóò tẹ̀lé e yóò pọ̀ púpọ̀. Ìdí tí Ọlọ́run fi fi àlá náà han fún Farao ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pé, Ọlọ́run ti pinnu pé yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ dandan, àti pé kò ni pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi ṣe é.