Eksodu 9:1-12

Eksodu 9:1-12 YCB

Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Lọ sọ fún Farao, ‘Èyí ni OLúWA Ọlọ́run àwọn Heberu sọ: “Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn Mí” Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, tí ó sì dá wọn dúró. Ọwọ́ OLúWA yóò mú ààrùn búburú wá sí ara ẹran ọ̀sìn nínú oko, sí ara ẹṣin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìbákasẹ, màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́ yín. Ṣùgbọ́n OLúWA yóò pààlà sí àárín ẹran ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti Israẹli àti ti àwọn ara Ejibiti tí yóò fi jẹ́ pé kò sí ẹran ọ̀sìn ti ó jẹ́ ti ará Israẹli tí yóò kùú.’ ” OLúWA sì dá àkókò kan wí pé, “Ní ọ̀la ni OLúWA yóò ṣe èyí ni ilẹ̀ yìí.” OLúWA sí ṣe é ni ọjọ́ kejì. Gbogbo ẹran ọ̀sìn ará Ejibiti kú, ṣùgbọ́n ẹyọ kan kò kú lára ẹran ọ̀sìn àwọn Israẹli. Farao rán àwọn ènìyàn rẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí, wọ́n sì rí pé ẹyọ kan kò kú lára àwọn ẹran ọ̀sìn ará Israẹli. Síbẹ̀ náà, Farao kò yí ọkàn rẹ̀ padà àti pé kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ. Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni, “Ẹ bu ẹ̀kúnwọ́ eérú gbígbóná láti inú ààrò, kí Mose kù ú sí inú afẹ́fẹ́ ni iwájú Farao. Yóò sì di eruku lẹ́búlẹ́bú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, yóò sì di oówo ti ń tú pẹ̀lú ìléròrò sí ara àwọn ènìyàn àti ẹran jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.” Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Farao. Mose sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran. Àwọn onídán kò le è dúró níwájú Mose nítorí oówo ti ó wà lára wọn àti ni ara gbogbo àwọn ara Ejibiti. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ ti Mose àti Aaroni, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti sọ fún Mose.