Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mose pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Aaroni ká, wọ́n sì wí pé, “Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa. Bí ó ṣe ti Mose tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.”
Aaroni dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bọ́ òrùka wúrà tí ó wà ní etí àwọn ìyàwó yín, tí àwọn ọmọkùnrin yín, àti tí àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ènìyàn bọ́ òrùka etí wọn, wọn sì kó wọn wá fún Aaroni. Ó sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ó sì fi ṣe ohun ọnà fínfín, ó sì dà á ní àwòrán ẹgbọrọ màlúù. Nígbà náà ni wọn wí pé, “Israẹli, wọ̀nyí ni òrìṣà, ti ó mú un yín jáde wá láti Ejibiti.”
Nígbà ti Aaroni rí èyí, ó kọ́ pẹpẹ kan níwájú ẹgbọrọ màlúù náà, ó sì kéde pé, “Lọ́la ni àjọyọ̀ sí OLúWA.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ àlàáfíà wá. Lẹ́yìn náà wọ́n jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣeré.
OLúWA sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú gòkè wá láti Ejibiti, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀. Wọ́n ti yí kánkán kúrò nípa ọ̀nà tí mo ti mo pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì ti dá ère ẹgbọrọ màlúù fún ara wọn. Wọ́n ti foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì ti rú ẹbọ sí i, wọ́n sì ti sọ pé, ‘Israẹli wọ̀nyí ní òrìṣà tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá.’ ”
OLúWA wí fún Mose pé, “Èmi ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn. Ǹjẹ́ nísinsin yìí fi mí sílẹ̀, nítorí kí ìbínú mi lè gbóná sí wọn, kí èmi sì lè pa wọ́n run. Nígbà náà ni èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.”