Eksodu 3:7-14

Eksodu 3:7-14 YCB

Ọlọ́run si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára. Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, igbe àwọn ará Israẹli ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Ejibiti ti ṣe ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, lọ, Èmi yóò rán ọ sí Farao láti kó àwọn ènìyàn Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.” Ṣùgbọ́n Mose wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Farao lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti?” Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mose pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún ọ, tí yóò fihàn pé Èmi ni ó rán ọ lọ; Nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí.” Mose sì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí mo bá tọ àwọn ará Israẹli lọ tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ tí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn ní ìgbà náà?” Ọlọ́run sì sọ fún Mose pé, “èMI NI TI ń Jẹ́ èMI NI. Èyí ni ìwọ yóò sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘èMI NI ni ó rán mi sí i yín.’ ”