6
Ègbé ni fún àwọn tí ara rọ̀
1Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni
àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria
àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè
tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá.
2Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó
kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì.
Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini.
Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ?
Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí?
3Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú,
ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí.
4Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe
ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn
ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ
ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ.
5Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi
ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin.
6Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan
àti ìkunra tí o dára jùlọ
ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro.
7Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn
pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn
àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò.
Olúwa Kórìíra Ìgbéraga Ọmọ Israẹli
8 Olúwa Olódùmarè ti búra fúnra rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé:
“Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu
n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀,
Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́
àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”
9Bí ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú. 10Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.”
11Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà,
Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú,
àti àwọn ilé kéékèèké sí wẹ́wẹ́.
12Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí?
Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀?
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé
ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.
13Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari,
ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba Karnaimu?”
14Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí pé,
“Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Israẹli,
wọn yóò pọ́n yín lójú ní gbogbo ọ̀nà,
láti Lebo-Hamati, títí dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah.”