2 Kọrinti Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìfáàrà sí ìwé àwọn ará Kọrinti kejì
Lẹ́tà Paulu àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọrinti kò yanjú àwọn ìṣòro tó wà láàrín wọn tán. Ó mú èso rere wá, ṣùgbọ́n ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe ṣí kù sílẹ̀. Ní pàtàkì jùlọ, Paulu ní láti yanjú ìṣòro tó jẹ mọ́ àṣẹ tí ó ń lò. Àwọn ara Kọrinti sì ń ṣe iyèméjì lórí Paulu ṣùgbọ́n Paulu kọ̀wé pẹ̀lú ìtara láti fi ìdí agbára àti àṣẹ tí ó ní gẹ́gẹ́ bí aposteli múlẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ó ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn Kristiani ní ibòmíràn tí wọ́n jẹ́ aláìní.
A rí ayọ̀ ìborí ìṣòro láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ìwé yìí. Bí Paulu ṣe ń sọ nípa wàhálà tí ó rí, àwọn ìyọrísí nínú iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristiani, fi hàn bí agbára Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́, tí ó yọ ohun rere láti inú ohun búburú. Nítòótọ́ èṣù ní agbára, ó ń wá ọ̀nà láti ba iṣẹ́ Ọlọ́run jẹ́, ṣùgbọ́n síbẹ̀ Ọlọ́run tóbi jù èṣù lọ, ó sì fi ẹsẹ̀ àwọn tó gbà á gbọ́ mulẹ̀.
Kókó-ọ̀rọ̀
Àwọn ìkíni 1.1-11.
Àwọn ọ̀rọ̀ ṣókí nípa iṣẹ́ Paulu 1.12–2.11.
Ìwàásù lórí ìríjú Kristiani 2.12–6.13.
Àwọn àkíyèsí Paulu 6.14–7.16.
Ọrẹ fún aláìní Judea 8.1–9.15.
Paulu sọ nípa àṣẹ tí ó ní gẹ́gẹ́ bí Aposteli 10.1–13.10.
Ohun tó kíyèsi gbẹ̀yìn 13.11-14.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

2 Kọrinti Ìfáàrà: BMYO

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀