1 Ọba 18:42-46

1 Ọba 18:42-46 BMYO

Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu gòkè lọ láti jẹ àti láti mu. Ṣùgbọ́n Elijah gun orí òkè Karmeli lọ ó sì tẹríba, ó sì fi ojú rẹ̀ sí agbede-méjì eékún rẹ̀. Ó sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ, kí o sì wo ìhà Òkun, òun sì gòkè lọ, ó sì wò.” Ó sì wí pé, “Kò sí nǹkan níbẹ̀.” Ó sì wí pé, “Tún lọ nígbà méje.” Nígbà keje, ìránṣẹ́ náà sì wí pé, “Àwọsánmọ̀ kékeré kan dìde láti inú Òkun, gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ènìyàn.” Elijah sì wí pé, “Lọ, kí o sọ fún Ahabu pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ, kí òjò ó má ba à dá ọ dúró.’ ” Ó sì ṣe, nígbà díẹ̀ sí i, ọ̀run sì ṣú fún àwọsánmọ̀, ìjì sì dìde, òjò púpọ̀ sì rọ̀, Ahabu sì gun kẹ̀kẹ́ lọ sí Jesreeli. Agbára OLúWA sì ń bẹ lára Elijah; ó sì di àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ, ó sì sáré níwájú Ahabu títí dé Jesreeli.