1 Ọba 17:1-5

1 Ọba 17:1-5 YCB

Elijah ará Tiṣibi láti Tiṣbi ní Gileadi wí fún Ahabu pé, “Bí OLúWA Ọlọ́run Israẹli ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, kì yóò sí ìrì tàbí òjò ní ọdún díẹ̀ tí ń bọ̀ bí kò ṣe nípa ọ̀rọ̀ mi.” Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ Elijah wá pé: “Kúrò níhìn-ín, kọjú sí ìhà ìlà-oòrùn, kí o sì fi ara rẹ pamọ́ níbi odò Keriti, tí ń bẹ níwájú Jordani. Ìwọ yóò mu nínú odò náà, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò láti máa bọ́ ọ níbẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti sọ fún un. Ó sì lọ sí ẹ̀bá odò Keriti, tí ń bẹ níwájú Jordani, ó sì dúró síbẹ̀.