1 Kronika Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé yìí jẹ́ àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àkókò, ohun tó fa ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe rí gan an. Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àkọkún àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tó wà nínú àwọn ìwé Samuẹli àti àwọn ìwé ọba. Gbogbo àwọn iṣẹ́ àti ìṣe àwọn ọba Israẹli àti Juda nì tí ó fi ara sin nínú àwọn ìwé tókù ni ó sọ àsọyé àti àṣọjinlẹ̀ wọn. Bákan náà ni ó sọ nípa àwọn wòlíì àti àlùfáà, ipa àti ipò wọn nígbà ayé ọba kan pàtó.
Ọ̀rọ̀ nípa àwọn ìgbèkùn Israẹli àti Juda ni ó jẹ ẹ́ lógún, ó sọ nípa ìyípadà tó bá ìgbé ayé wọn ní ìgbèkùn tí wọ́n wà. Ọ̀pọ̀ ohun tó ń mú ọkàn wọn pòruurù ni pé, wọn kò mọ bí Ọlọ́run ṣe ní ìfẹ́ sí wa sí? Ǹjẹ́ májẹ̀mú Ọlọ́run ṣì wà lórí wọn? Ǹjẹ́ ìlérí fún ìran Dafidi ọba ní ìtumọ̀ nípa wọn ní àsìkò tí wọn wà ní abẹ́ ìṣèjọba ilẹ̀ Pasia yìí, Àti ì bà ṣe pọ̀ wo ni ó wa láàrín wọn àti gbogbo àwọn àròkàn wọ̀nyí ni ìwé yìí wá ìdáhùn fún?
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìpìlẹ̀ ẹ̀yà Heberu 1.1-54.
ii. Àwọn ọmọ Jakọbu méjìlá àti ìdílé Juda 2.1–4.23.
iii. Àwọn ọmọ Simoni, Reubeni Gadi àti Manase 4.24-25.
iv. Lefi àti ìdílé wọn àti àwọn ìdílé mìíràn. 6–9.
v. Ikú Saulu àti gbígba Jerusalẹmu 10–12.
vi. Gbígba àpótí ẹ̀rí Olúwa padà 13–16.
viii. Ìdílé ọba tí a ṣe ìlérí fún 17–29.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

1 Kronika Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀