Sek 7:9-10

Sek 7:9-10 YBCV

Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Dá idajọ otitọ, ki ẹ si ṣe ãnu ati iyọ́nu olukuluku si arakunrin rẹ̀. Má si ṣe ni opó lara, tabi alainibaba, alejo, tabi talakà; ki ẹnikẹni ninu nyin ki o máṣe gbèro ibi li ọkàn si arakunrin rẹ̀.