Rom 8:15-17
Rom 8:15-17 YBCV
Nitori ẹnyin kò tun gbà ẹmí ẹrú lati mã bẹ̀ru mọ́: ṣugbọn ẹnyin ti gbà ẹmí isọdọmọ, nipa eyi ti awa fi nke pé, Abba, Baba. Ẹmí tikararẹ̀ li o mba ẹmí wa jẹrí pe, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe: Bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi; biobaṣepe awa bá a jìya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rẹ̀.





