Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, iwọ li emi ngbadura mi si, Oluwa, ni igba itẹwọgba: Ọlọrun, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ da mi lohùn, ninu otitọ igbala rẹ. Yọ mi kuro ninu ẹrẹ̀, má si ṣe jẹ ki emi ki o rì: gbigbà ni ki a gbà mi lọwọ awọn ti o korira mi, ati ninu omi jijìn wọnni. Máṣe jẹ ki kikún-omi ki o bò mi mọlẹ, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki ọgbun ki o gbé mi mì, ki o má si ṣe jẹ ki iho ki o pa ẹnu rẹ̀ de mọ́ mi. Oluwa, da mi lohùn; nitori ti iṣeun ifẹ rẹ dara, yipada si mi gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ irọnu ãnu rẹ. Ki o má si ṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara iranṣẹ rẹ: emi sa wà ninu ipọnju; yara, da mi lohùn. Sunmọ ọkàn mi, si rà a pada: gbà mi nitori awọn ọta mi. Iwọ ti mọ̀ ẹ̀gan mi ati ìtiju mi, ati alailọla mi: gbogbo awọn ọta mi li o wà niwaju rẹ. Ẹgan ti bà mi ni inu jẹ; emi si kún fun ikãnu: emi si woye fun ẹniti yio ṣãnu fun mi, ṣugbọn kò si; ati fun awọn olutunu, emi kò si ri ẹnikan. Nwọn fi orõro fun mi pẹlu li ohun jijẹ mi; ati li ongbẹ mi nwọn fun mi li ọti kikan ni mimu.
Kà O. Daf 69
Feti si O. Daf 69
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 69:13-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò