Iru awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ti a dè ninu ipọnju ati ni irin; Nitori ti nwọn ṣọ̀tẹ si ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn si gàn imọ Ọga-ogo: Nitorina o fi lãla rẹ̀ aiya wọn silẹ: nwọn ṣubu, kò si si oluranlọwọ. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn. O mu wọn jade kuro ninu òkunkun ati ojiji ikú, o si fa ìde wọn ja. Enia iba ma yìn Oluwa: nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia. Nitori ti o fọ ilẹkun idẹ wọnni, o si ke ọpa-idabu irin wọnni li agbedemeji. Aṣiwere nitori irekọja wọn, ati nitori ẹ̀ṣẹ wọn, oju npọ́n wọn. Ọkàn wọn kọ̀ onjẹ-konjẹ; nwọn si sunmọ́ eti ẹnu-ọ̀na ikú. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn. O rán ọ̀rọ rẹ̀, o si mu wọn lara da, o si gbà wọn kuro ninu iparun wọn. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia. Si jẹ ki nwọn ki o ru ẹbọ ọpẹ, ki nwọn ki o si fi orin ayọ̀ sọ̀rọ iṣẹ rẹ̀.
Kà O. Daf 107
Feti si O. Daf 107
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 107:10-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò