Owe 4:4-7

Owe 4:4-7 YBCV

On si kọ́ mi pẹlu, o si wi fun mi pe, jẹ ki aiya rẹ ki o gbà ọ̀rọ mi duro: pa ofin mi mọ́ ki iwọ ki o si yè. Ni ọgbọ́n, ni oye: máṣe gbagbe; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fà sẹhin kuro li ọ̀rọ ẹnu mi. Máṣe kọ̀ ọ silẹ, yio si mu ọ tọ́: fẹ ẹ, yio si pa ọ mọ́. Ipilẹṣẹ ọgbọ́n ni lati ni ọgbọ́n: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye.