Filp 4:17-19

Filp 4:17-19 YBCV

Kì iṣe nitoriti emi nfẹ ẹ̀bun na: ṣugbọn emi nfẹ eso ti yio mã di pupọ nitori nyin. Ṣugbọn mo ni ohun gbogbo, mo si ti di pupọ: mo si kún nigbati mo ti gbà nkan wọnni ti a ti rán lati ọdọ nyin wá lọwọ Epafroditu, ọrẹ olõrùn didùn, ẹbọ itẹwọgbà, ti iṣe inu didùn gidigidi si Ọlọrun. Ṣugbọn Ọlọrun mi yio pèse ni kikún fun gbogbo aini nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ rẹ̀ ninu ogo ninu Kristi Jesu.