PAULU ati Timotiu, awọn iranṣẹ Jesu Kristi, si gbogbo awọn enia mimọ́ ninu Kristi Jesu ti o wà ni Filippi, pẹlu awọn biṣopu ati awọn diakoni: Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Oluwa Jesu Kristi. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi fun gbogbo iranti nyin ti mo nṣe, Nigbagbogbo ninu gbogbo adura mi fun nyin li emi nfi ayọ̀ bẹ̀bẹ, Nitori ìdapọ nyin ninu ihinrere lati ọjọ kini wá titi fi di isisiyi. Ohun kan yi sa da mi loju, pe ẹniti o ti bẹ̀rẹ iṣẹ rere ninu nyin, yio ṣe aṣepe rẹ̀ titi fi di ọjọ Jesu Kristi: Gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati rò eyi fun gbogbo nyin, nitoriti ọkàn nyin wà lọdọ mi, niwọn bi o ti ṣepe gbogbo nyin ni iṣe alabapin ore-ọfẹ pẹlu mi ninu idè mi ati ninu idahùn-ẹjọ mi ati ifẹsẹmulẹ ihinrere. Nitori Ọlọrun li ẹlẹri mi, bi mo ti nṣafẹri nyin to gidigidi ninu iyọ́nu Jesu Kristi.
Kà Filp 1
Feti si Filp 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Filp 1:1-8
5 Days
The letter Paul wrote to the church in Philippi has traveled across generations to nourish and challenge our hearts and minds today. This five-day devotional gives you a taste of the book of Philippians, many centuries from when God authored it through Paul. May God fill you with wonder and expectation as you read this letter of joy! Because these are not just Paul’s words to an ancient church—these are God’s words to you.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò