Mat 27:57-66

Mat 27:57-66 YBCV

Nigbati alẹ si lẹ, ọkunrin ọlọrọ̀ kan ti Arimatea wá, ti a npè ni Josefu, ẹniti on tikararẹ̀ iṣe ọmọ-ẹhin Jesu pẹlu: O tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. Nigbana ni Pilatu paṣẹ ki a fi okú na fun u. Josefu si gbé okú na, o si fi aṣọ ọ̀gbọ mimọ́ dì i, O si tẹ́ ẹ sinu iboji titun ti on tikararẹ̀, eyi ti a gbẹ ninu apata: o si yi okuta nla di ẹnu-ọ̀na ibojì na, o si lọ. Maria Magdalene si wà nibẹ̀, ati Maria keji, nwọn joko dojukọ ibojì na. Nigbati o di ọjọ keji, eyi ti o tẹ̀le ọjọ ipalẹmọ, awọn olori alufa, ati awọn Farisi wá pejọ lọdọ Pilatu, Nwọn wipe, Alàgba, awa ranti pe ẹlẹtan nì wi nigbati o wà lãye pe, Lẹhin ijọ mẹta, emi o jinde. Nitorina paṣẹ ki a kiyesi ibojì na daju titi yio fi di ijọ kẹta, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ máṣe wá li oru, nwọn a si ji i gbé lọ, nwọn a si wi fun awọn enia pe, O jinde kuro ninu okú: bẹ̃ni ìṣina ìkẹhìn yio si buru jù ti iṣaju. Pilatu wi fun wọn pe, Ẹnyin ní oluṣọ: ẹ mã lọ, ẹ ṣe e daju bi ẹ ti le ṣe e. Bẹ̃ni nwọn lọ, nwọn si se iboji na daju, nwọn fi edídí dí okuta na, nwọn si yàn iṣọ.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ