Mat 21:1-5

Mat 21:1-5 YBCV

NIGBATI nwọn sunmọ eti Jerusalemu, ti nwọn de Betfage li òke Olifi, nigbana ni Jesu rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji lọ. O wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin, lọgan ẹnyin o ri kẹtẹkẹtẹ kan ti a so ati ọmọ rẹ̀ pẹlu: ẹ tú wọn, ki ẹ si fà wọn fun mi wá. Bi ẹnikẹni ba si wi nkan fun nyin, ẹnyin o wipe, Oluwa ni ifi wọn ṣe; lọgán ni yio si rán wọn wá. Gbogbo eyi li a ṣe, ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu wolĩ wá ki o le ṣẹ, pe, Ẹ sọ fun ọmọbinrin Sioni pe, Kiyesi i, Ọba rẹ mbọ̀ wá sọdọ rẹ, o ni irẹlẹ, o joko lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ