Mat 15:16-20

Mat 15:16-20 YBCV

Jesu si wipe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye sibẹ? Ẹnyin ko mọ̀ pe, ohunkohun ti o ba bọ si ẹnu lọ si inu, a si yà a jade? Ṣugbọn nkan wọnni ti o ti ẹnu jade, inu ọkàn li o ti wá; nwọn a si sọ enia di alaimọ́. Nitori lati inu ọkàn ni iro buburu ti ijade wá, ipania, panṣaga, àgbere, olè, ẹ̀rí èké ati ọ̀rọ buburu; Ohun wọnyi ni isọ enia di alaimọ́: ṣugbọn ki a jẹun li aiwẹwọ́ kò sọ enia di alaimọ́.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ