Joṣ 19:1-16

Joṣ 19:1-16 YBCV

IPÍN keji yọ fun Simeoni, ani fun ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni gẹgẹ bi idile wọn; ilẹ-iní wọn si wà lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Juda. Nwọn si ní Beeri-ṣeba, tabi Ṣeba, ati Molada, ni ilẹ-iní wọn; Ati Hasari-ṣuali, ati Bala, ati Esemu; Ati Eltoladi, ati Bẹtulu, ati Horma; Ati Siklagi, ati Beti-markabotu, ati Hasari-susa; Ati Beti-lebaotu, ati Ṣaruheni; ilu mẹtala pẹlu ileto wọn: Aini, Rimmoni, ati Eteri, ati Aṣani; ilu mẹrin pẹlu ileto wọn: Ati gbogbo ileto ti o yi ilu wọnyi ká dé Baalati-beeri, Rama ti Gusù. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni gẹgẹ bi idile wọn. Ninu ipín awọn ọmọ Juda ni awọn ọmọ Simeoni ni ilẹ-iní: nitori ipín awọn ọmọ Juda pọ̀ju fun wọn: nitorina ni awọn ọmọ Simeoni fi ní ilẹ-iní lãrin ilẹ-iní wọn. Ilẹ kẹta yọ fun awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn: àla ilẹ-iní wọn si dé Saridi: Àla wọn gòke lọ si ìha ìwọ-õrùn, ani titi o fi dé Marala, o si dé Dabaṣeti; o si dé odò ti mbẹ niwaju Jokneamu; O si ṣẹri lati Saridi lọ ni ìha ìla-õrùn si ìla-õrùn dé àla Kisloti-tabori; o si yọ si Daberati; o si jade lọ si Jafia; Ati lati ibẹ̀ o kọja ni ìha ìla-õrùn si Gati-heferi, dé Ẹti-kasini; o si yọ si Rimmoni titi o fi dé Nea; Àla na si yi i ká ni ìha ariwa dé Hannatoni: o si yọ si afonifoji Ifta-eli; Ati Katati, ati Nahalali, ati Ṣimroni, ati Idala, ati Beti-lehemu: ilu mejila pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.