Hos 7:3-16

Hos 7:3-16 YBCV

Nwọn fi ìwa-buburu wọn mu ki ọba yọ̀; nwọn si fi eké wọn mu awọn ọmọ-alade yọ̀. Gbogbo nwọn ni panṣagà, bi ãrò ti alakàra mu gboná, ti o dawọ́ kikoná duro, lẹhìn igbati o ti pò iyẹ̀fun tan, titi yio fi wú. Li ọjọ ọba wa, awọn ọmọ-alade ti fi oru ọti-waini mu u ṣaisàn; o nà ọwọ́ rẹ̀ jade pẹlu awọn ẹlẹgàn. Nitori nwọn ti mura ọkàn wọn silẹ bi ãrò, nigbati nwọn ba ni buba: alakàra wọn sùn ni gbogbo oru; li owurọ̀ o jo bi ọwọ́-iná. Gbogbo wọn gboná bi ãrò, nwọn ti jẹ awọn onidajọ wọn run; gbogbo ọba wọn ṣubu: kò si ẹnikan ninu wọn ti o ke pè mi. Efraimu, on ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ awọn enia na; Efraimu ni akàra ti a kò yipadà. Awọn alejò ti jẹ agbara rẹ̀ run, on kò si mọ̀: nitõtọ, ewú wà kakiri li ara rẹ̀, sibẹ̀ on kò mọ̀. Igberaga Israeli si njẹri si i li oju rẹ̀; nwọn kò si yipadà si Oluwa Ọlọrun wọn, bẹ̃ni fun gbogbo eyi nwọn kò si wá a. Efraimu pẹlu dabi òpe adàba ti kò li ọkàn; nwọn kọ si Egipti, nwọn lọ si Assiria. Nigbati nwọn o lọ, emi o nà àwọn mi le wọn; emi o mu wọn wá ilẹ bi ẹiyẹ oju-ọrun; emi o nà wọn, bi ijọ-enia wọn ti gbọ́. Egbe ni fun wọn! nitori nwọn ti sá kuro lọdọ mi: iparun ni fun wọn! nitori nwọn ti ṣẹ̀ si mi: bi o tilẹ ṣepe mo ti rà wọn padà, ṣugbọn nwọn ti ṣe eké si mi. Nwọn kò si ti fi tọkàntọkàn ké pè mi, nigbati nwọn hu lori akete wọn: nwọn kó ara wọn jọ fun ọkà ati ọti-waini, nwọn si ṣọ̀tẹ si mi. Bi mo ti dì, ti mo si fun apa wọn li okun, sibẹ̀ nwọn nrò ibi si mi. Nwọn yipadà, ṣugbọn kì iṣe si Ọga-ogo: nwọn dàbi ọrun ẹtàn; awọn ọmọ-alade wọn yio tipa idà ṣubu, nitori irúnu ahọn wọn: eyi ni yio ṣe ẹsín wọn ni ilẹ Egipti.