Hos 11

11
Ìfẹ́ Ọlọrun sí Àwọn Eniyan Rẹ̀, Ọlọ̀tẹ̀
1NIGBATI Israeli wà li ọmọde, nigbana ni mo fẹ́ ẹ, mo si pè ọmọ mi lati Egipti jade wá.
2Bi nwọn ti pè wọn, bẹ̃ni nwọn lọ kuro lọdọ wọn: nwọn rubọ si Baalimu, nwọn si fi turari joná si ere fifin.
3Mo kọ́ Efraimu pẹlu lati rìn, mo dì wọn mu li apa, ṣugbọn nwọn kò mọ̀ pe mo ti mu wọn lara dá.
4Mo fi okùn enia fà wọn, ati idè ifẹ: mo si ri si wọn bi awọn ti o mu ajàga kuro li ẹrẹkẹ wọn, mo si gbe onjẹ kalẹ niwaju wọn.
5On kì yio yipadà si ilẹ Egipti, ṣugbọn ara Assiria ni yio jẹ ọba rẹ̀, nitori nwọn kọ̀ lati yipadà.
6Idà yio si ma gbe inu ilu rẹ̀, yio si run ìtikun rẹ̀, yio si jẹ wọn run, nitori ìmọran ara wọn.
7Awọn enia mi si tẹ̀ si ifàsẹhin kuro lọdọ mi: bi o tilẹ̀ ṣepe nwọn pè wọn si Ọga-ogo jùlọ, nwọn kò jùmọ gbe e ga.
8Emi o ha ṣe jọwọ rẹ lọwọ, Efraimu? emi o ha ṣe gbà ọ silẹ, Israeli? emi o ha ti ṣe ṣe ọ bi Adma? emi o ha ti ṣe gbe ọ kalẹ bi Seboimu, ọkàn mi yi ninu mi, iyọnu mi gbiná pọ̀.
9Emi kì yio mu gbigboná ibinu mi ṣẹ, emi kì yio yipadà lati run Efraimu: nitori Ọlọrun li emi, kì iṣe enia; Ẹni-Mimọ lãrin rẹ: emi kì yio si wá ninu ibinu.
10Nwọn o ma tẹ̀le Oluwa: on o ke ramùramù bi kiniun: nigbati on o ke, nigbana li awọn ọmọ yio wariri lati iwọ-õrun wá.
11Nwọn o warìri bi ẹiyẹ lati Egipti wá, ati bi adàba lati ilẹ Assiria wá: emi o si fi wọn si ile wọn, li Oluwa wi.
Ìdájọ́ lórí Juda ati Israẹli
12Efraimu fi eke sagbàra yi mi ka, ile Israeli si fi ẹtàn sagbàra yi mi ka: ṣugbọn Juda njọba sibẹ̀ pẹlu Ọlọrun, o si ṣe olõtọ pẹlu Ẹni-mimọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Hos 11: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀