Gẹn 23

23
1SARA si di ẹni ẹtadilãdoje ọdún: iye ọdún aiye Sara li eyi.
2Sara si kú ni Kirjat-arba; eyi na ni Hebroni ni ilẹ Kenaani: Abrahamu si wá lati ṣọ̀fọ Sara ati lati sọkun rẹ̀.
3Abrahamu si dide kuro niwaju okú rẹ̀, o si sọ fun awọn ọmọ Heti, wipe,
4Alejò ati atipo li emi iṣe lọdọ nyin: ẹ fun mi ni ilẹ-isinku lãrin nyin, ki emi ki o le sin okú mi kuro ni iwaju mi.
5Awọn ọmọ Heti si dá Abrahamu lohùn, nwọn si wi fun u pe,
6Oluwa mi, gbọ́ ti wa: alagbara ọmọ-alade ni iwọ lãrin wa: ninu ãyò bojì wa ni ki o sin okú rẹ; kò sí ẹnikẹni ninu wa ti yio fi ibojì rẹ̀ dù ọ, ki iwọ ki o má sin okú rẹ.
7Abrahamu si dide duro, o si tẹriba fun awọn enia ilẹ na, fun awọn ọmọ Heti.
8O si ba wọn sọ̀rọ wipe, Bi o ba ṣe pe ti inu nyin ni ki emi ki o sin okú mi kuro ni iwaju mi, ẹ gbọ́ ti emi, ki ẹ si bẹ̀ Efroni, ọmọ Sohari, fun mi,
9Ki o le fun mi ni ihò Makpela, ti o ni, ti o wà li opinlẹ oko rẹ̀; li oju-owo ni ki o fifun mi, fun ilẹ-isinku lãrin nyin.
10Efroni si joko lãrin awọn ọmọ Heti: Efroni, ọmọ Heti, si dá Abrahamu lohùn li eti gbogbo awọn ọmọ Heti, ani li eti gbogbo awọn ti nwọ̀ ẹnubode ilu rẹ̀ wipe,
11Bẹ̃kọ, Oluwa mi, gbọ́ ti emi, mo fi oko na fun ọ, ati ihò ti o wà nibẹ̀, mo fi fun ọ: li oju awọn ọmọ awọn enia mi ni mo fi i fun ọ: sin okú rẹ.
12Abrahamu si tẹriba niwaju awọn enia ilẹ na.
13O si wi fun Efroni, li eti awọn enia ilẹ na pe, Njẹ bi iwọ o ba fi i fun mi, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ti emi: emi o san owo oko na fun ọ; gbà a lọwọ mi, emi o si sin okú mi nibẹ̀.
14Efroni si da Abrahamu li ohùn, o wi fun u pe,
15Oluwa mi, gbọ́ ti emi: irinwo òṣuwọn ṣekeli fadaka ni ilẹ jẹ; kili eyini lãrin temi tirẹ? sa sin okú rẹ.
16Abrahamu si gbọ́ ti Efroni; Abrahamu si wọ̀n iye fadaka na fun Efroni, ti o sọ li eti awọn ọmọ Heti, irinwo òṣuwọn ṣekeli fadaka, ti o kọja lọdọ awọn oniṣòwo.
17Oko Efroni ti o wà ni Makpela, ti o wà niwaju Mamre, oko na, ati ihò ti o wà ninu rẹ̀, ati gbogbo igi ti o wà ni oko na, ti o wà ni gbogbo ẹba rẹ̀ yika, li a ṣe daju,
18Fun Abrahamu ni ilẹ-ini, li oju awọn ọmọ Heti, li oju gbogbo awọn ti nwọ̀ ẹnubode ilu rẹ̀.
19Lẹhin eyi li Abrahamu sin Sara, aya rẹ̀, ninu ihò oko Makpela, niwaju Mamre: eyi nã ni Hebroni ni ilẹ Kenaani.
20Ati oko na, ati ihò ti o wà nibẹ̀, li a ṣe daju fun Abrahamu, ni ilẹ isinku, lati ọwọ́ awọn ọmọ Heti wá.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Gẹn 23: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa