II. Sam 16:11-12

II. Sam 16:11-12 YBCV

Dafidi si wi fun Abiṣai, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, ọmọ mi ti o ti inu mi wá, nwá ẹmi mi kiri: njẹ melomelo ni ara Benjamini yi yio si ṣe? jọwọ rẹ̀, si jẹ ki o ma yan ẽbu; nitoripe Oluwa li o fi rán an. Bọ́ya Oluwa yio wo ipọnju mi, Oluwa yio si fi ire san a fun mi ni ipo ẽbu rẹ̀ loni.