I. Kor 2:7-9

I. Kor 2:7-9 YBCV

Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n Ọlọrun ni ijinlẹ, ani ọgbọ́n ti o farasin, eyiti Ọlọrun ti làna silẹ ṣaju ipilẹṣẹ aiye fun ogo wa: Eyiti ẹnikẹni ninu awọn olori aiye yi kò mọ̀: nitori ibaṣepe nwọn ti mọ̀ ọ, nwọn kì ba ti kàn Oluwa ogo mọ agbelebu. Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ, pe, Ohun ti oju kò ri, ati ti etí kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pèse silẹ fun awọn ti o fẹ ẹ.