I. Kor 12:7-10

I. Kor 12:7-10 YBCV

Ṣugbọn a nfi ifihàn Ẹmí fun olukuluku enia lati fi jère. Nitoriti a fi ọ̀rọ ọgbọ́n fun ẹnikan nipa Ẹmí; ati fun ẹlomiran ọ̀rọ-ìmọ nipa Ẹmí kanna; Ati fun ẹlomiran igbagbọ́ nipa Ẹmí kanna; ati fun ẹlomiran ẹ̀bun imularada nipa Ẹmí kanna; Ati fun ẹlomiran iṣẹ iyanu iṣe; ati fun ẹlomiran isọtẹlẹ; ati fun ẹlomiran ìmọ ẹmí yatọ; ati fun ẹlomiran onirũru ède; ati fun ẹlomiran itumọ̀ ède