ROMU 8:3-4
ROMU 8:3-4 YCE
Èyí jẹ́ nǹkan tí kò ṣe é ṣe lábẹ́ Òfin, nítorí eniyan kò lè ṣàì dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe é, nígbà tí ó dá ẹ̀bi ikú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu ẹ̀yà ara eniyan. Àní sẹ́, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí eniyan ẹlẹ́ṣẹ̀ láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́. Ọlọrun ṣe èyí kí á lè tẹ̀lé ìlànà Òfin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àní àwa tí ìhùwàsí wa kì í ṣe bíi tí ẹni tí ẹran-ara ń lò ṣugbọn bí àwọn ẹni tí Ẹ̀mí ń darí.





