ROMU 2:6-11

ROMU 2:6-11 YCE

Ọlọrun yóo san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀; yóo fi ìyè ainipẹkun fún àwọn tí ń fi sùúrù ṣe iṣẹ́ rere nípa lílépa àwọn nǹkan tí ó lógo, tí ó sì lọ́lá, àwọn nǹkan tí kò lè bàjẹ́. Ṣugbọn ní ti àwọn tí ó jẹ́ pé ti ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, ati àwọn tí kò gba òtítọ́, àwọn tí wọ́n gba ohun burúkú, Ọlọrun yóo fi ibinu ati ìrúnú rẹ̀ hàn wọ́n; yóo mú ìpọ́njú ati ìṣòro bá gbogbo àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ ibi. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ kàn, lẹ́yìn náà àwọn Giriki. Ṣugbọn yóo fi ògo, ọlá ati alaafia fún gbogbo àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ fún, lẹ́yìn náà yóo fún àwọn Giriki. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju.