ORIN DAFIDI 64
64
Adura Ààbò
1Ọlọrun, gbọ́ ìráhùn mi;
pa mí mọ́ lọ́wọ́ ìdẹ́rùbà ọ̀tá;
2dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan burúkú;
kó mi yọ lọ́wọ́ ète àwọn aṣebi.
3Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,
wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ burúkú bí ẹni ta ọfà;
4wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí aláìṣẹ̀ láti ibùba wọn,
láìbẹ̀rù, wọ́n ń ta ọfà ọ̀rọ̀ sí i lójijì.
5Wọ́n wonkoko mọ́ ète burúkú wọn;
wọ́n ń gbìmọ̀ àtidẹ okùn sílẹ̀ níkọ̀kọ̀,
wọ́n ń rò lọ́kàn wọn pé, “Ta ni yóo rí wa?
6Ta ni yóo wá ẹ̀ṣẹ̀ wa rí?
Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí ni a ti fi pète.”
Áà, inú ọmọ eniyan jìn!
7Ṣugbọn Ọlọrun yóo ta wọ́n lọ́fà;
wọn óo fara gbọgbẹ́ lójijì.
8Yóo pa wọ́n run nítorí ohun tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ;
gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn ni yóo máa mirí nítorí wọn.
9Ẹ̀rù yóo sì ba gbogbo eniyan;
wọn yóo máa sọ ohun tí Ọlọrun ti gbé ṣe,
wọn yóo sì máa ronú nípa iṣẹ́ rẹ̀.
10Kí àwọn olódodo máa yọ̀ ninu OLUWA,
kí wọ́n sì máa wá ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀!
Kí gbogbo ẹni pípé máa ṣògo.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 64: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010