ORIN DAFIDI 37:1-13

ORIN DAFIDI 37:1-13 YCE

Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú; má sì jowú àwọn aṣebi; nítorí pé kíákíá ni wọn yóo gbẹ bí i koríko; wọn óo sì rọ bí ewé. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere. Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́. Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA; yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́. Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ. Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀; ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan. Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún; tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é. Yẹra fún ibinu; sì yàgò fún ìrúnú. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná; ibi ni àyọrísí rẹ̀. Nítorí pé a óo pa àwọn eniyan burúkú run; ṣugbọn àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ni yóo jogún ilẹ̀ náà. Ẹ fún eniyan burúkú ní ìgbà díẹ̀ sí i, yóo pòórá; ẹ̀ báà wá a títí ní ààyè rẹ̀, kò ní sí níbẹ̀. Ṣugbọn àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóo jogún ilẹ̀ náà: wọn óo máa gbádùn ara wọn; wọn óo sì ní alaafia lọpọlọpọ. Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo; ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè. Ṣugbọn OLUWA ń fi eniyan burúkú rẹ́rìn-ín, nítorí ó mọ̀ pé ọjọ́ ìparun rẹ̀ ń bọ̀.