Kí ló dé tí o fi jìnnà réré, OLUWA, tí o sì fara pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú? Pẹlu ìgbéraga ni eniyan burúkú fi ń dọdẹ àwọn aláìní; jẹ́ kí ó bọ́ sinu tàkúté tí ó fi àrékérekè dẹ. Eniyan burúkú ń fọ́nnu lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, Ó ń bu ọlá fún wọ̀bìà, ó sì ń kẹ́gàn OLUWA. Eniyan burúkú kò wá Ọlọrun, nítorí ìgbéraga ọkàn rẹ̀, kò tilẹ̀ sí ààyè fún Ọlọrun ninu gbogbo ìrònú rẹ̀. Nígbà gbogbo ni nǹkan ń dára fún un. Ìdájọ́ rẹ, Ọlọrun, ga pupọ, ó ju òye rẹ̀ lọ; ó ń yọ ṣùtì ètè sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó ń rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé, kò sí ohun tí ó lè bi òun ṣubú, ati pé ní gbogbo ọjọ́ ayé òun, òun kò ní ní ìṣòro. Ẹnu rẹ̀ kún fún èpè, ẹ̀tàn ati ìhàlẹ̀; ìjàngbọ̀n ati ọ̀rọ̀ ibi sì wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀. Ó ń lúgọ káàkiri létí abúlé, níbi tó fara pamọ́ sí ni ó ti ń pa àwọn aláìṣẹ̀; ó ń fojú ṣọ́ àwọn aláìṣẹ̀ tí yóo pa. Ó fara pamọ́ bíi kinniun tí ó wà ní ibùba; ó fara pamọ́ láti ki aláìní mọ́lẹ̀; ó mú aláìní, ó sì fi àwọ̀n fà á lọ. Ó wó aláìṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ó tẹ orí wọn ba, ó sì fi agbára bì wọ́n ṣubú. Ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun ti gbàgbé, OLUWA ti gbé ojú kúrò, kò sì ní rí i laelae.”
Kà ORIN DAFIDI 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 10:1-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò