ÌWÉ ÒWE 26
26
1Bí yìnyín kò ṣe yẹ ní àkókò ooru,
ati òjò ní àkókò ìkórè,
bẹ́ẹ̀ ni iyì kò yẹ òmùgọ̀.
2Bí ológoṣẹ́ tí ń rábàbà kiri,
ati bí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń fò ká,
bẹ́ẹ̀ ni èpè tí kò nídìí, kì í balẹ̀ síbìkan.
3Bí pàṣán ti rí lára ẹṣin, tí ìjánu sì rí lẹ́nu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
bẹ́ẹ̀ ni igi rí lẹ́yìn àwọn òmùgọ̀.
4Má ṣe dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀,
kí ìwọ pàápàá má baà dàbí rẹ̀.
5Dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà agọ̀ rẹ̀,
kí ó má baà rò pé òun gbọ́n lójú ara òun.
6Ẹni tí ó rán òmùgọ̀ níṣẹ́ gé ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀,
ó sì ń mu omi ìjàngbọ̀n.
7Bí ẹsẹ̀ arọ, tí kò wúlò,
ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀.
8Bí ẹni fi òkúta sinu kànnàkànnà,
ni ẹni tí ń yẹ́ òmùgọ̀ sí rí.
9Bí ẹ̀gún tí ó gún ọ̀mùtí lọ́wọ́,
ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀.
10Ẹni tí ó gba òmùgọ̀ tabi ọ̀mùtí sí iṣẹ́
dàbí tafàtafà tí ń pa eniyan lára kiri.
11Bí ajá tíí pada sídìí èébì rẹ̀#2 Pet 2:22
bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ tó pada sí ìwà agọ̀ rẹ̀.
12Ìrètí ń bẹ fún òmùgọ̀
ju ẹni tí ó gbọ́n lójú ara rẹ̀ lọ.
13Ọ̀lẹ ń wí pé, “Kinniun kan wà lọ́nà!
Kinniun buburu kan wà ní ìgboro!”
14Bí ìlẹ̀kùn ṣe ń ṣí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ìdè rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ibùsùn rẹ̀.
15Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ,
ṣugbọn ó lẹ kọjá kí ó lè bu oúnjẹ kí ó fi bọ ẹnu.
16Ọ̀lẹ gbọ́n lójú ara rẹ̀
ju eniyan meje tí wọ́n lè dáhùn ọ̀rọ̀ pẹlu ọgbọ́n lọ.
17Ẹni tí ó ti ọrùn bọ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀,
dàbí ẹni tí ó gbá ajá alájá létí mú.
18Bíi aṣiwèrè tí ó ju igi iná tabi ọfà olóró,
19ni ẹni tó ṣi ẹlòmíràn lọ́nà,
tí ó wá ń sọ pé “Mo kàn ń ṣeré ni!”
20Láìsí igi, iná óo kú,
bẹ́ẹ̀ ni, láìsí olófòófó, ìjà óo tán.
21Bí èédú ti rí sí ògúnná, ati igi sí iná,
bẹ́ẹ̀ ni oníjà eniyan rí, sí àtidá ìjà sílẹ̀.
22Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùn
a máa wọni lára ṣinṣin.
23Ètè mímú ati inú burúkú,
dàbí ìdàrọ́ fadaka tí a yọ́ bo ìkòkò amọ̀.
24Ẹni tí ó bá kórìíra eniyan,
lè máa fi ọ̀rọ̀ ẹnu bo ara rẹ̀ láṣìírí,
ṣugbọn ẹ̀tàn wà ninu rẹ̀,
25bí ó bá sọ̀rọ̀ dáradára, má ṣe gbà á gbọ́,
nítorí ọpọlọpọ ìríra kún inú ọkàn rẹ̀.
26Ó lè gbìyànjú láti fi ẹ̀tàn pa àrankàn rẹ̀ mọ́,
ṣugbọn ìwà burúkú rẹ̀ yóo hàn ní àwùjọ gbogbo eniyan.
27Ẹni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ni yóo já sinu rẹ̀,#Sir 27:25-27
ẹni tí ó bá sì ń yí òkúta ni òkúta yóo pada yí lù.
28A-purọ́-mọ́ni a máa kórìíra àwọn tí ń parọ́ mọ́,
ẹni tí ń pọ́nni sì lè fa ìparun ẹni.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌWÉ ÒWE 26: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010