Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀, ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni. Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi. Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀, ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu. Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀, ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun. Èrò ọkàn olódodo dára, ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú. Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là. A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun, ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin. À máa ń yin eniyan gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe gbọ́n tó, ṣugbọn ọlọ́kàn àgàbàgebè yóo di ẹni ẹ̀gàn.
Kà ÌWÉ ÒWE 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌWÉ ÒWE 12:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò